KADGIS s’alaye ipinnu lati bi ile Asofin Hunkuyi wo ni Kaduna
Ifiga-gbaga oun aawo to wa laarin awon ogbontarigi ninu egbe oselu onigbale ni’pinle Kaduna ti ba ona miran yo o.
Alakoso eka ti nse amojuto idagbasoke Ipinle Kaduna, Hussaini Ibrahim ti fi to awon oniroyin leti lojo Isegun ose yii ni ilu Kaduna wipe, bibi ile Asofin ti n soju Guusu Kaduna nilu Abuja, Suleiman Othman Hunkuyi wo ko ni nkan se pelu aawo to wa ninu egbe oselu APC nipinle naa.
Awon ti n seto idagbasoke ni Ipinle Kaduna ti a mo si Kaduna State Urban Planning Development Agency (KASUPDA), ni kutukutu owuro ojo Isegun ose yii, fi ero katakata wo ile Asofin naa pelu esun wipe o je ijoba ipinle lowo-gbe fun odun bi mejo seyin.
Hussein Ibrahim fi kun n wipe, ijoba Ipinle ti gba lati gba ile naa lowo Asofin Hunkuyi ati wipe, yio so o di ibi igbafe fun awon eniyan agbegbe naa laipe
Hussein wa gba awon olugbe ipinle Kaduna niyanju lati ri i wipe, won gba gbogbo iwe ti o ye lori dukia won ni ipinle naa lati ma ri pipon oju ijoba.
Sugbon sa, Asofin Hunkuyi figi gun-un wipe, Gomina Nasir El-Rufai kopa pataki ninu bibi ile re wo pelu atileyin awon omo ogun kogberegbe ti won ha ra won gaga pelu ohun elo oloro ki o to lo ba Aare Muhammadu Buhari nipinle Adamawa.
LATI OWO OLOOTU