O kere tan enia meje gbemi mi lojiji latari laasigbo iyanre ni’lu Kaduna
(Apeere)
KADUNA, NIGEEIA – Ileese Olopa ni Oluulu ipinle Kaduna ti fidi re mule wipe ko din ni eniyan meje ototo ti won gbemi mi ti awon meedogun miran si farapa yanna-yanna latari aawo to waye laarin awon odo langba awon elesin Larubawa ati Onigbagbo latari pe a n ba ra eni dore po.
(Summary: Kaduna State Police Command on Monday evening confirmed that seven persons were sent to their early grave, 15 critically injured as a result of violent clashes that erupted between Christian and Muslim youths at Kasuwan Magani in Kajuru local government area of Kaduna State.)
Nigba to n fi koko isele naa han fun awon akoroyin ni’lu Kaduna ni asaale ojo Aje ti isele oun se, Alukoro fun eka Olopa ipinle naa, Mukhtar Aliyu fi kun n pe, opolopo ilegbee ati ibitaja lo faragba ninu isele laabi ohun ti won si jona gudugudu laarin wakati die ti daru-dapo ohun fi wa’ye.
Gege bi oro re, ASP Aliyu fi kun n pe, ilese olopa nipinle naa ti my ohun gbogbo bosipo ladugbo naa ati wipe igba keji oga agba Olopa nipinle naa ti ta kobo si adugbo naa latiri wipe ohun gbogbo mbe labe akoso ijoba.
Okan ninu awon koko pataki to s’okun fa gbonmisi omioto naa ni esun ti won fi kan awon elesin Larubawa wipe won n fi tipa-tikuuku so awon osoro omoge awon elesin Kristieni di Larubawa eleyi to si ti n fa awuyewuye laarin awon olugbe ilu naa niwon igba die seyin.
Sugbon sa, alaafia ti pada si agbegbe naa latari igbese ti awon osise alaabo nipinle ohun gbe lati ri wipe ohun gbogbo pada sipo bi t’ateyin wa.
Bakanna, Gomina fun ipinle Kaduna, Ogbeni Nasir El-Rufai ti ke gbajari lati ri wipe owo te gbogbo awon ti won kopa ninu isele buburu ohun ki won si foju bale ejo.
Gomina El-Rufai wa ba awon eniyan agbegbe naa kedun latari isele laabi ohun bakanna losi tenu mo wipe, ijoba oun ko ni f’ayegba katikati kankan.
O wa ro awon olugbe agbegbe ohun lati gbe ni ife ati alaafia ki idagbasoke baa le waya.
LATI OWO OLOOTU